Friday, December 6, 2019

Ọ̀gbẹ́ni àti omidan ọ̀sẹ̀ tó yááyì jùlọ

A yan Saheed Fatimah gẹ́gẹ́ bíi omidan to múra jùlọ àti Ògúnníyì Adédayọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀gbẹ́ni tó wọ aṣọ àṣà tó dára jùlọ nínú ìpàdé ètò ìgbáradì fún ọ̀sẹ̀ àṣà wa èyí tó ń bọ̀ lọ́nà ní kò pẹ́ kò jìnà.
 Èyí wáyé láti lè mú kí àṣà ìwọsọ wa láwùjọ Yorùbá má baà parun àti pàápàá láti gbé àṣà wa ga. Àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù tí a sì ṣe èyí láti mú gbogbo àwọn tó kù mọ ìwúlò àti iyì tó wà nínú kí a máa wọ aṣọ ìbílẹ̀ wa ní gbogbo ìgbà.
  A wá fi àsìkò yìí bẹ gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-o-jíire láti gbìyànjú nínú à ń gbé àṣà wa lárugẹ kí ó má baà parun. Alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá á gbè wá o (Àṣẹ)

    Àwòrán Ọ̀gbẹ́ni ọ̀sẹ̀ tó yááyì julọ
Ògúnníyì Adédayọ̀
ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù

Àwòrán omidan ọ̀sẹ̀ tó yááyì julọ
Saheed Fatimah
ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù

Àwòrán àwọn Ọ̀gbẹ́ni àti omidan ẹgbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn 


Omidan àti Ọ̀gbẹ́ni àṣà ẹgbẹ́ 





0 comments:

Post a Comment

ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
Yosa Unilorin (c)2019