Monday, December 23, 2019

O kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òní Kuranga Halimat Abodunde

Ará igbó , èrò ọ̀nà ẹ sáré tètè wà bá wa yọ̀ òní lọjọ́-ìbí Abodunde Ọpẹ́ lọ́wọ ọba oníbú ọrẹ fún oore ẹ̀mí gígùn.
Abodunde, pẹpẹ lọ̀wú sáré àtẹ̀pẹ́ lẹsẹ̀ e tọ̀nà ní re ní re làá sọ̀rọ̀ atare.
        Orógbó ló ní kí o gbó, igi ọ̀pẹ ló ní kí o pẹ́, Ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóní kí gbà ó dẹ̀ ọ́ lọ́rùn. Wàá pẹ́, wàá sì gbélé ayé ṣe rere.



Wednesday, December 18, 2019

O kú ọjọ́ ìbí òní Omidan Àṣà Christiana

Òní ni ọjọ́ ìbí Omidan Oke Christiana, aṣojú réré lo jẹ́ àwokọ́se rere lo sì  jẹ́ fún gbogbo ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá níbi ká wọṣọ àṣà Yorùbá  Ọ̀gá ni kánwú láwùjọ okùta Ọ̀gá ni omidan Tiana níbi ká wọṣọ àṣà Yoruba, Ọ̀gá ni níbi kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.
Gbogbo ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún igbe lárugẹ àṣà àti ìṣẹ̀ṣẹ Yoruba wọn sì kí ọ kú ọjọ́ ìbí





Thursday, December 12, 2019

O kú ọjọ́ ìbí òní Boluwatife

 Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ló ń bá ẹ yọ̀ tí wọ́n kí ọ kú oriire òní, wọ́n ní o òní kánjú kú, o òní mọ ìnira láyé rẹ, ọdún èyí yóò jẹ ọ̀tun nínú ayé rẹ nítorí pé
Ọdọọdún là ń rórógbó
Ọdọọdún là ń ráwùsá
Ọdọọdún là ń rọ́mọ obì lórí àtẹ

O ku oriire òní Boluwatife



Ìgbáradì ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹhu fún ayẹyẹ ọdún àṣà tí yóò wáyé ní simẹ́sítà tó ń bọ̀

Ìgbáradì ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹhu fún ayẹyẹ ọdún àṣà tí yóò wáyé ní simẹ́sítà tó ń bọ̀

Gbogbo lẹ́bùrù ló fi orin sẹ́nu tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ ra ijó

Ní nkan bíi agogo méjì ó kọjá ìṣẹ́jú díẹ̀ ni ìgbáradì náà bẹ̀rẹ̀.

Aní àwọn ọ̀gá bí Ọ̀mọ̀wé Omolayọ̀ Ọ̀gunlọlá àti Ìyáàfin Taiwo Babátúndé ní ìkàlẹ̀

Àwọn àwòrán tí a yà ní bi ìgbáradì náà:















Monday, December 9, 2019

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá lápapọ̀ kí Oluwakemisola kú oriire ọjọ́ ìbí

Òní ni ọjọ́ ìbí Omidan Olawumi Oluwakemisola Olúwa Toyin
Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè ló ń bá ẹ yọ̀ tí wọ́n kí ọ kú oriire òní, wọ́n ní o òní kánjú kú, o òní mọ ìnira láyé rẹ, ọdún èyí yóò jẹ ọ̀tun nínú ayé rẹ nítorí pé
Ọdọọdún là ń rórógbó
Ọdọọdún là ń ráwùsá
Ọdọọdún là ń rọ́mọ obì lórí àtẹ
O ku oriire òní

Friday, December 6, 2019

Ọ̀gbẹ́ni àti omidan ọ̀sẹ̀ tó yááyì jùlọ

A yan Saheed Fatimah gẹ́gẹ́ bíi omidan to múra jùlọ àti Ògúnníyì Adédayọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀gbẹ́ni tó wọ aṣọ àṣà tó dára jùlọ nínú ìpàdé ètò ìgbáradì fún ọ̀sẹ̀ àṣà wa èyí tó ń bọ̀ lọ́nà ní kò pẹ́ kò jìnà.
 Èyí wáyé láti lè mú kí àṣà ìwọsọ wa láwùjọ Yorùbá má baà parun àti pàápàá láti gbé àṣà wa ga. Àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù tí a sì ṣe èyí láti mú gbogbo àwọn tó kù mọ ìwúlò àti iyì tó wà nínú kí a máa wọ aṣọ ìbílẹ̀ wa ní gbogbo ìgbà.
  A wá fi àsìkò yìí bẹ gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-o-jíire láti gbìyànjú nínú à ń gbé àṣà wa lárugẹ kí ó má baà parun. Alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá á gbè wá o (Àṣẹ)

    Àwòrán Ọ̀gbẹ́ni ọ̀sẹ̀ tó yááyì julọ
Ògúnníyì Adédayọ̀
ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù

Àwòrán omidan ọ̀sẹ̀ tó yááyì julọ
Saheed Fatimah
ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù

Àwòrán àwọn Ọ̀gbẹ́ni àti omidan ẹgbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn 


Omidan àti Ọ̀gbẹ́ni àṣà ẹgbẹ́ 





ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
Yosa Unilorin (c)2019