Sunday, April 12, 2020

Ìmọ̀ràn pàtàkì lórí àrùn Covid-19

Tiwa làṣà!

Láti lè dẹ́kun àjàkálẹ̀-àrùn kórokòro tí ń jà ràn-ìn-ràn-ìn káàkiri àgbáyé. Àwa olóyè ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ti Yunifásitì Ìlọrin ń ránwa létí pé:
Kí a tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀ fún wa láti lè dẹ́kun àtànkárí àjàkálẹ̀-àrùn kórokòro tí ń jà ràn-ìn-ràn-ìn káàkiri àgbáyé.

1. 🏘Kí a gbélé ní ìwọ̀nba àsìkò tí ìjọba ní kí ìgbélé ó wà. kí a sì yàgò fún òde tí àgbáríjọpọ̀ àwọn ènìyàn wà níbẹ̀.

2. 😷Kí a rántí lo ìbomú tí àwọn elétò ìlera ti làkalẹ̀ fún wa láti máa lò fi bo imú àti ẹnu wa.

3.Kí a ri dájú pé a fọwọ́ wa lóòrekóòrè pẹ̀lú ọṣẹ àti omi tó mọ́ tóní-tóní, kí a sì nu ọwọ́ wa pẹ̀lú ohun aporó àjàkálẹ̀-àrùn tí àwọn elétò ìlera ti là kalẹ̀ fún wa láti máa lò. Kí a sì ri dájú pé àyíká wa mọ́ tóní-tóní.

4. 🤫🥱kí a dẹ́kun ìwà-ìbàjẹ́ kí a máa fọwọ́ romú, kí a máa fọwọ́ sẹ́nu, kí a máa fọwọ́ nu ojú, tàbí kí a máa fọwọ́ ro etí.

5. 💃🏽_2miles_🕺🏽 Kí o ri dájú pé ó kéré tán máìlì méjì ni àlàfo tó wà láàárín ìwọ àti ẹnìjejì rẹ.

6.😤🤧 Kí a ri dájú pé a fi ààlà-ibi-ìgúnpá fi bo imú àti ẹnu wa bí a báa ń sín tàbí hú ikọ́.

7. 🤝🏽👫🏼Kí a yàgò fún bíbawọ́ tàbí dídìmọ́ra-ẹni fún ìgbà díẹ̀.☎ 🚑 Kí a sì pe àwọn dókítà tàbí àwọn àjọ elétò ìlera bí a bá ní àwọn àpẹẹrẹ àárẹ̀ kankan lára.

8.🛒 Kí àwọn ẹbí kọ̀ọ̀kan yan ẹnìkan tí yóò máa jáde lọ sọ́jà lọ ra ohun tí a bá fẹ́ rà.

9.🚪🗝 Bí a bá sì fẹ́ ṣí ìlẹ̀kùn wọlé tàbí jáde, yálà ìlẹ̀kùn ilé, ìlẹ̀kùn ọkọ̀, tàbí òmìíràn, kí a wọ gílọ́fù ìbowọ́ wa tàbí kí a ri dájú pé ìnuwọ́ wà lọ́wọ́ wa kí a tó ṣí ìlẹ̀kùn náà.

10.💕 Paríparí gbogbo rẹ̀, kí a fi ìfẹ́ hàn sí ara wa, láìgbàgbé àwọn tí ó  ní àjàkálẹ̀-àrùn tó fẹ́ gba ìgboro ayé yìí lára.


Gbogbo àwa olóyè Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀-èdè Yorùbá ti Yunifásitì Ìlọrin sì kí gbogbo wa pé;
Ẹ kú ìgbélé o.
A ò sì ní fi àárẹ̀ lògbà láṣẹ Èdùmàrè. (Igbá-kejì Ààrẹ)

Ìlera yín tó jẹwá lógún, ló mú kí a ránwa létí pé Ìmọ́tótó ló lè ṣẹ́gun àrùn gbogbo (Ààrẹ)

láti ẹnu;
Salaudeen Jamaldeen Opẹ́yẹmí
 OJ-Lion
 Ààrẹ (YOSA)

 ```Ṣí ọwọ́``` ;
Ọwọ́-òkadé Michael 
 M.K.O
 Akọ̀wé àgbà(YOSA)

 Olùkéde
Ẹṣọ̀run-Jésùjẹ́nyọ̀ Ìyanuolúwa
 Hyper Jay
 Alukoro (YOSA)

Ìgbà Ọ̀tun yóò tù wá lára o!

0 comments:

Post a Comment

ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
Yosa Unilorin (c)2019