Tuesday, June 2, 2020

Kò s'óhun tó jọ ṣíṣí iléèwé padà lọ́wọ́ yìí- Ìjọba àpapọ̀

Ijọba apapọ ni titpa lawọn ileewe yoo ṣi wa bayii nitori bi iye awọn to n ni arun naa ṣe n fojojumọ gogo sii lorilẹede Naijiria.

Igbimọ amuṣẹya ti ijsba apapọ gbe kalẹ lori arun coronavirus lo sọ bẹẹ lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlawọn oniroyin.

Igbesẹ naa si wa lara awọn igbesẹ to wa nilẹ eyi ti igbims naa ni, pẹlu ifọwọsi aarẹ muhammadu Buhari, ṣi n tẹsiwaju.

Ọmọ pupa làwọn olólùfẹ́ wa fẹ́ wò nínú fíìmù làwọn òṣèré tíátà fi ń bóra- Muka Ray

Yoruba ni oju kii ri arẹwa ko ma kii, oju to ba sì rẹwa, o di dandan ko pawo wale.

Idi ree ti ọpọ awọn oṣere tiata lobinrin fi n lo ipara ibora ki wọn lee pupa ni awọ, ti oju wọn yoo si dun wo ninu ere.
Gbajumọ oṣere tiata kan Muka Ray Eyiwunmi lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto kan loju opo ikanni BBC Yoruba.

Ènìyàn 416 ló ti lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Ọjọ́ Ajé ní Naijiria

Ajọ NCDC ti kede eniyan 416 gẹgẹ bi apapọ eniyan to ni arun Coronavirus lorilẹede Naijiria ni Ọjọ Aje lorilẹede Naijiria.
Ajọ NCDC naa fi ikede naa si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn, ti apapọ awọn eniyan to ni arun naa ti wa da 10578.

Majek Fashek, gbajúgbajà akọrin Raggae jáde láyé lẹ́ni ọdún 57

Gbajugbaja akọrin raggae ni, Majẹkodunmi Fasheke ti ọpọ mọ si 'Majek Fashek' ti jade laye. Iroyin to n tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe aṣalẹ ọjọ Aje lo dagbere pe o digboṣe.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni Majek Fashek ki o to dagbere faye.

ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
Yosa Unilorin (c)2019