
Ará igbó , èrò ọ̀nà ẹ sáré tètè wà bá wa yọ̀ òní lọjọ́-ìbí Abodunde Ọpẹ́ lọ́wọ ọba oníbú ọrẹ fún oore ẹ̀mí gígùn.
Abodunde, pẹpẹ lọ̀wú sáré àtẹ̀pẹ́ lẹsẹ̀ e tọ̀nà ní re ní re làá sọ̀rọ̀ atare.
Orógbó ló ní kí o gbó, igi ọ̀pẹ ló ní kí o pẹ́, Ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóní kí gbà ó dẹ̀ ọ́ lọ́rùn. Wàá pẹ́, wàá sì gbélé ayé ṣe rere.
...