Monday, February 21, 2022

[BIOGRAPHY] DR. OMOLEWU, Olatubosun Christopher

 


NAME:   OMOLEWU, Olatubosun Christopher
EMAIL:   omolewuolatubosun@gmail.com
omolewu@yahoo.com


SCHOOLS ATTENDED
Oluwole Primary School, Akoka, Lagos 1985 - 1990
St. Finbarr’s College, Akoka, Lagos 1990 - 1996
University of Ilorin, Ilorin 2004 - 2007
University of Ilorin, Ilorin  2011- 2013


ACADEMIC QUALIFICATIONS:
Date Awarding Institutions
M.A. (Yoruba Language) 2013 University of Ilorin

B.A. (Hons) First Class in Yoruba 2007 University of Ilorin
                     
Nigeria Certificate in Education 2001 
 Federal College of Education, Osiele, Abeokuta.

SSCE (O/Level) 2003 NECO

WASCE (O/Level) 1996 WAEC

PROFESSIONAL QUALIFICATION AND DIPLOMAS
Certificate in Data Processing and Management Information System.
Computer Services and Information Technology Directorate, University of Ilorin, Ilorin. 2009

Nigeria Certificate in Education.
Federal College of Education, Osiele Abeokuta, 2001

SCHOLARSHIP AND PRIZES
Best Overall Performance Student Prize, Faculty of Arts, University of Ilorin, 2006/2007 session.

Best performed student prize. Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, 2006/2007 session.


HONOURS, DISTINCTIONS, AND MEMBERSHIP OF LEARNED/PROFESSIONAL SOCIETIES

(a) Honours and Distinction

   (1)   Certificate of commendation by the Federal College of Education 
      Okene, Kogi State   -   2009.

  (b) Membership of Learned/Professional Societies

(1) 2015 –Date Yorùbá Creative Writers Association of Nigeria.
(2) 2010 – Date Linguistics Association of Nigeria (LAN)
(3) 2002 – Date Association of Teachers of the Yorùbá Language and 
Culture of Nigeria.  
(4) 2002 – Date Yoruba Studies Association of Nigeria (YSAN)

PUBLICATIONS:

(1) Omolewu, O.C. (2020): Fífi Gírámà-Olófin Ìyídà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Àwọn Fọ́nrán Ìhun Inú Gbólóhùn Gírámà Yorùbá. ALÓRE: Ilorin Journal of the Humanities. Vol. 29, 100-129, 43-71, Published by Faculty of Arts, University of Ilorin, Ilorin. 



(2) Omolewu, O.C. (2017): A Morphosyntactic Analysis of Yorùbá Names: An X-Bar theory Approach. CENTERPOINT JOURNAL (Humanities Edition): A Journal of Intellectual, Scientific and Cultural Interest. Vol. 20, 1-26, Published by the University of Ilorin Library and Publications Committee, University of Ilorin, Ilorin. Available online at http://www.unilorin.edu.ng/ejournals/index.php/cp


            
(3) Omolewu, O.C. (2017): Wh-Movement Constructions in Ẹ̀gbá Dialect of Yorùbá. ALÓRE: Ilorin Journal of the Humanities. Vol. 26, 100-129, Published by Faculty of Arts, University of Ilorin, Ilorin. 



(4) Omolewu, O.C. (2014): A Survey of Some Phonological Features of Ìbàràpá  Dialect of Yorùbá. IJLLC: Ilorin Journal of Linguistics, Literature and Culture. Vol. 4, 58-83, Published by Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin. 



(5) Omolewu, O.C. (2013): Àfiwé Atọ́ka ‘kò’, ‘kọ́’ àti ‘kì í’ nínú Ìhun Ìyísódì Yorùbá Àjùmọ̀lò àti ti Ẹ̀ka-èdè Ẹ̀gbá. IJLLC: Ilorin Journal of Linguistics, Literature and Culture. Vol. 3, 132-156, Published by Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin.



(6) Omolewu, O.C.  (2016):  Dídá Àbá Ìwádìí. Ọgbọ́n Ìṣèwádìí Nínú Ìmọ̀ Ẹ̀dá-
Èdè, Lítíréṣọ̀ àti Àṣà Yorùbá, Published by Department of Linguistics and 
Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin, pp. 35-61.



(7) Adeosun, H.O. & Omolewu, O.C. (2016): Ọ̀nà Ìṣàkójọ, Ìtúpalẹ̀, àti Àgbékalẹ̀ 
Èròjà Àmúkalẹ̀ Fáyẹ̀wò Nínú Iṣẹ́ Ìwádìí. Ọgbọ́n Ìṣèwádìí Nínú Ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdé, Lítíréṣọ̀ àti Àṣà Yorùbá, Published by Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin, pp. 148-173.




(8) Omolewu, O.C. (2014): Focus Constructions and Negation of Focused 
Constituents in Ẹ̀gbá Dialect. Bringing Our Cultures Home: FESTSCHRIFT FOR BADE AJAYI AT 70, Published by Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin, pp. 312-334.



(9) Omolewu, O.C. (2014): Àlàyé Lórí Àwọn Kókó inú Tíọ́rì Gírámà. Bringing 
Our Cultures Home: FESTSCHRIFT FOR BADE AJAYI AT 70, Published by Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Ilorin, pp. 281-298.



(10) Omolewu, O.C. (2021): The Syntax of Focus and Relative Clause Constructions in Yorùbá Proverbs. Nasara Journal of Humanities. Published by Faculty of Arts, Nasarawa State University, Keffi. Vol. 10, No.1, 146-157.


(11) Omolewu, O.C. (2019): Òfin Ìhun Gbólóhùn àti Àpólà Gbólóhùn. Láàńgbàsà: Jọ́nà iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá. Published by Department of Linguistics, African and Asian Studies, University of Lagos, No. 21, 90-180. 


(12) Omolewu, O.C. (2019): Ọládẹ̀jọ Òkédìjí Pẹ̀yìndà. Nínú Dúró Adélékè, S.M Ráji àti Bámijí Òjó (Eds.) Ọládẹ̀jọ Òkédìjí: Ewì Ìrántí. Ẹgbẹ́ Òǹkọ̀wé Yorùbá (Yorùbá Writers Association), Department of Linguistics and African Languages, University of Ìbàdàn, Ìbàdàn. Pp. 81-87. 


(13) Omolewu, O.C. (2018): Ipa Òfin Ìyídà Nínú Orúkọ Yorùbá: Àlàyé Ní Ìlànà Tíọ́rì Onípele. Obitun: Journal of the Humanities. Published by Faculty of Arts, Ekiti State University, Ado-Ekiti. Vol. 9, 197-209. 


(14) Friday-Otun, J.O. & Omolewu, O.C. (2017): Commiserating through Proverbs among the Yorùbá: A Pragmatic Analysis. YORÙBÁ: Journal of Yoruba Studies Association of Nigeria. Vol. 8 (3): 51-78, Published by Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan.



(15) Omolewu, O.C. (2015): Àfihàn Èrò Dúró Adélékè Lórí Ìṣẹ̀lẹ̀ Àwùjọ Nàìjíríà Nínú Ìwé Ewì Aṣọ Ìgbà. YORÙBÁ GBÒDE: Jọ́nà Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àsà Yorùbá, Nàìjíríà. Vol. 5 (5): 91-108, Published by the Association of the Teachers of Yorùbá Language and Culture of Nigeria, Department of Linguistics and Languages, Adékúnlé Ajásin University, Àkùngbá Àkókó.



(16) Omolewu, O.C. (2012): Ìṣesí Atọ́ka ‘Má’ Nínú Yorùbá Àjùmọ̀lò àti Ẹ̀ka-
èdè Ẹ̀gbá. Láàńgbàsà: Jọ́nà iṣẹ́ Akadá ní Èdè Yorùbá. No. 16, 1-17, Published by Department of Linguistics, African and Asian Studies, University of Lagos.



(17) Omolewu, O.C. (2012): Ìhà tí Lítíréṣọ̀ Yorùbá kọ sí Ìṣèjọba àti Ìdàgbàsókè Ilẹ̀ Nàìjíríà: Ẹ̀rí Láti Inú Ààrẹ-ọ̀nà Kakanfò, Ọ̀gá Nìyá Mi àti Kò Sáyè Láàfin. YORÙBÁ: Journal of Yoruba Studies Association of Nigeria. Vol. 7 (1): 79-103, Published by Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá, Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan.



(18) Omolewu, O.C. (2012): Lámèyítọ́ Eré Fíìmù Ajẹmọ́ Rògbòdìyàn: J’ógun Ó
Mí Láti Ọwọ́ Àníkẹ́ Bọ́lá Obot Gẹ́gẹ́ Bí Àpẹẹrẹ. YORÙBÁ GBÒDE: Jọ́nà Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè àti Àsà Yorùbá, Nàìjíríà. Vol. 5 (2): 88-98, Published by the Association of the Teachers of Yorùbá Language and Culture of Nigeria, Department of Linguistics and Languages, Adékúnlé Ajásin University, Àkùngbá Àkókó



.
(19) Omolewu, O.C. (2001): Yorùbá Religion: Dead or Alive? In Language Use and Preservation: A Festschrift in Honour of Prof. Abel Gbenga Fakuade Published by Department of Linguistics and Nigerian Languages, University of Ilorin, Nigeria. In collaboration with Department of English and Literary Studies, Ekiti State University, Ado-Ekiti and Department of Information Technology, Modibbo Adama University, Yola. pp 330-340.



(20) Friday-Otun, J.O. & Omolewu, O.C. (2017): Analysis of Collocative Words in Yorùbá Language Usage. Yorùbá Studies in a challenging word: A Festschrift in Honour of Olúgbóyèga Àlàbá, Published by Department of Linguistics, African and Asian Studies, University of Lagos, pp 421-441.



(21) Omolewu, O.C. (2017): Olúgbóyèga Àlàbá, Onímọ̀ Ìjìnlẹ̀ èrò Nípa Ilé-ayé: Ẹ̀rí láti inú Onírúurú Àròfọ̀ àti Àṣàyàn Àròfọ̀. Yorùbá Studies in a challenging word: A Festschrift in Honour of Olúgbóyèga Àlàbá, Published by Department of Linguistics, African and Asian Studies, University of Lagos, pp 736-758.



(22) Omolewu, O.C. (2016): Àṣà Ìbílẹ̀ Yorùbá Nínú Àwọn Ìtàn-Àròsọ Fágúnwà: Ẹ̀kọ́ Fún Orílẹ̀-Èdè Nàìjíríà. Òtun Ìmọ̀ Nínú Ìtàn-Àròsọ D.O. Fágúnwà (New Findings in the Novels of D. O. Fágúnwà), Published by Yoruba Studies Association of Nigeria. Department of Linguistics and African Languages, University of Ibadan, pp. 218-234.



 (23) Friday-Otun, J.O. & Omolewu, O.C. (2016): Collocative Syntagms in the Yorùbá Language Usage. Language Discourse & Society. Vol. 4, 2(8); 94-118, Published by the Language & Society, Research Committee 25 of the International Sociological Association, University Campus Suffolk, United Kingdom. Available online at http://www.language-and-society.org/journal



(24) Sanusi, I.O. & Omolewu, O.C. (2016): Comparative and Analysis of Negative Constructions in Standard Yoruba and Egba Dialect. Drumspeak: International Journal of Research in the Humanities¸NEW SERIES (online), Vol. 5 No2, pp. 101-128, Published by Faculty of Arts, University of Cape Coast, Ghana. https://journal.ucc.edu.gh/index.php/drum speak/article/view/236



(25) Omolewu, O.C. (2021): African Wisdom In Proverbs: The Yorùbá Example.
Being and Becoming African as a Permanent Work in Progress: Inspiration From Chinua Achebe’s Proverbs. Cameroon: Langaa Research & Publishing Common Initiative Group, pp. 209-232. Publisher’s web address, www.langaa-rpcig.net



(26) Omolewu, O.C. (2017): Taboo. Culture and Customs of the Yorùbá. Austin: Pan-African University Press. USA, pp. 445-454. Publisher’s web address, www.panafricanuniversitypress.com



 (27) Omolewu, O. C. (2020): Àwọn Àròfọ̀ Ọmọ Ṣàbi Apá Kìíní. Ìbàdàn: Joytal Press and Publications, pp 1-120.



(28) Omolewu, O. C. (2020): Àwọn Àròfọ̀ Ọmọ Ṣàbi Apá Kejì. Ìbàdàn: Joytal Press and Publications, pp 1-134.



(29) Omolewu, O. C. (2013): Talẹ́ Ló Jù. Ìbàdàn: Clemeve Media Konsult, pp. 1-73.

Tuesday, June 2, 2020

Kò s'óhun tó jọ ṣíṣí iléèwé padà lọ́wọ́ yìí- Ìjọba àpapọ̀

Ijọba apapọ ni titpa lawọn ileewe yoo ṣi wa bayii nitori bi iye awọn to n ni arun naa ṣe n fojojumọ gogo sii lorilẹede Naijiria.

Igbimọ amuṣẹya ti ijsba apapọ gbe kalẹ lori arun coronavirus lo sọ bẹẹ lasiko ifọrọwerọ rẹ pẹlawọn oniroyin.

Igbesẹ naa si wa lara awọn igbesẹ to wa nilẹ eyi ti igbims naa ni, pẹlu ifọwọsi aarẹ muhammadu Buhari, ṣi n tẹsiwaju.

Ọmọ pupa làwọn olólùfẹ́ wa fẹ́ wò nínú fíìmù làwọn òṣèré tíátà fi ń bóra- Muka Ray

Yoruba ni oju kii ri arẹwa ko ma kii, oju to ba sì rẹwa, o di dandan ko pawo wale.

Idi ree ti ọpọ awọn oṣere tiata lobinrin fi n lo ipara ibora ki wọn lee pupa ni awọ, ti oju wọn yoo si dun wo ninu ere.
Gbajumọ oṣere tiata kan Muka Ray Eyiwunmi lo sisọ loju ọrọ yii lasiko to n kopa lori eto kan loju opo ikanni BBC Yoruba.

Ènìyàn 416 ló ti lùgbàdì àrùn Coronavirus ní Ọjọ́ Ajé ní Naijiria

Ajọ NCDC ti kede eniyan 416 gẹgẹ bi apapọ eniyan to ni arun Coronavirus lorilẹede Naijiria ni Ọjọ Aje lorilẹede Naijiria.
Ajọ NCDC naa fi ikede naa si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn, ti apapọ awọn eniyan to ni arun naa ti wa da 10578.

Majek Fashek, gbajúgbajà akọrin Raggae jáde láyé lẹ́ni ọdún 57

Gbajugbaja akọrin raggae ni, Majẹkodunmi Fasheke ti ọpọ mọ si 'Majek Fashek' ti jade laye. Iroyin to n tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe aṣalẹ ọjọ Aje lo dagbere pe o digboṣe.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni Majek Fashek ki o to dagbere faye.

Sunday, April 12, 2020

Ìmọ̀ràn pàtàkì lórí àrùn Covid-19

Tiwa làṣà!

Láti lè dẹ́kun àjàkálẹ̀-àrùn kórokòro tí ń jà ràn-ìn-ràn-ìn káàkiri àgbáyé. Àwa olóyè ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ti Yunifásitì Ìlọrin ń ránwa létí pé:
Kí a tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin tí ìjọba gbé kalẹ̀ fún wa láti lè dẹ́kun àtànkárí àjàkálẹ̀-àrùn kórokòro tí ń jà ràn-ìn-ràn-ìn káàkiri àgbáyé.

1. 🏘Kí a gbélé ní ìwọ̀nba àsìkò tí ìjọba ní kí ìgbélé ó wà. kí a sì yàgò fún òde tí àgbáríjọpọ̀ àwọn ènìyàn wà níbẹ̀.

2. 😷Kí a rántí lo ìbomú tí àwọn elétò ìlera ti làkalẹ̀ fún wa láti máa lò fi bo imú àti ẹnu wa.

3.Kí a ri dájú pé a fọwọ́ wa lóòrekóòrè pẹ̀lú ọṣẹ àti omi tó mọ́ tóní-tóní, kí a sì nu ọwọ́ wa pẹ̀lú ohun aporó àjàkálẹ̀-àrùn tí àwọn elétò ìlera ti là kalẹ̀ fún wa láti máa lò. Kí a sì ri dájú pé àyíká wa mọ́ tóní-tóní.

4. 🤫🥱kí a dẹ́kun ìwà-ìbàjẹ́ kí a máa fọwọ́ romú, kí a máa fọwọ́ sẹ́nu, kí a máa fọwọ́ nu ojú, tàbí kí a máa fọwọ́ ro etí.

5. 💃🏽_2miles_🕺🏽 Kí o ri dájú pé ó kéré tán máìlì méjì ni àlàfo tó wà láàárín ìwọ àti ẹnìjejì rẹ.

6.😤🤧 Kí a ri dájú pé a fi ààlà-ibi-ìgúnpá fi bo imú àti ẹnu wa bí a báa ń sín tàbí hú ikọ́.

7. 🤝🏽👫🏼Kí a yàgò fún bíbawọ́ tàbí dídìmọ́ra-ẹni fún ìgbà díẹ̀.☎ 🚑 Kí a sì pe àwọn dókítà tàbí àwọn àjọ elétò ìlera bí a bá ní àwọn àpẹẹrẹ àárẹ̀ kankan lára.

8.🛒 Kí àwọn ẹbí kọ̀ọ̀kan yan ẹnìkan tí yóò máa jáde lọ sọ́jà lọ ra ohun tí a bá fẹ́ rà.

9.🚪🗝 Bí a bá sì fẹ́ ṣí ìlẹ̀kùn wọlé tàbí jáde, yálà ìlẹ̀kùn ilé, ìlẹ̀kùn ọkọ̀, tàbí òmìíràn, kí a wọ gílọ́fù ìbowọ́ wa tàbí kí a ri dájú pé ìnuwọ́ wà lọ́wọ́ wa kí a tó ṣí ìlẹ̀kùn náà.

10.💕 Paríparí gbogbo rẹ̀, kí a fi ìfẹ́ hàn sí ara wa, láìgbàgbé àwọn tí ó  ní àjàkálẹ̀-àrùn tó fẹ́ gba ìgboro ayé yìí lára.


Gbogbo àwa olóyè Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀-èdè Yorùbá ti Yunifásitì Ìlọrin sì kí gbogbo wa pé;
Ẹ kú ìgbélé o.
A ò sì ní fi àárẹ̀ lògbà láṣẹ Èdùmàrè. (Igbá-kejì Ààrẹ)

Ìlera yín tó jẹwá lógún, ló mú kí a ránwa létí pé Ìmọ́tótó ló lè ṣẹ́gun àrùn gbogbo (Ààrẹ)

láti ẹnu;
Salaudeen Jamaldeen Opẹ́yẹmí
 OJ-Lion
 Ààrẹ (YOSA)

 ```Ṣí ọwọ́``` ;
Ọwọ́-òkadé Michael 
 M.K.O
 Akọ̀wé àgbà(YOSA)

 Olùkéde
Ẹṣọ̀run-Jésùjẹ́nyọ̀ Ìyanuolúwa
 Hyper Jay
 Alukoro (YOSA)

Ìgbà Ọ̀tun yóò tù wá lára o!

Monday, December 23, 2019

O kú ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òní Kuranga Halimat Abodunde

Ará igbó , èrò ọ̀nà ẹ sáré tètè wà bá wa yọ̀ òní lọjọ́-ìbí Abodunde Ọpẹ́ lọ́wọ ọba oníbú ọrẹ fún oore ẹ̀mí gígùn.
Abodunde, pẹpẹ lọ̀wú sáré àtẹ̀pẹ́ lẹsẹ̀ e tọ̀nà ní re ní re làá sọ̀rọ̀ atare.
        Orógbó ló ní kí o gbó, igi ọ̀pẹ ló ní kí o pẹ́, Ọ̀gẹ̀dẹ̀ lóní kí gbà ó dẹ̀ ọ́ lọ́rùn. Wàá pẹ́, wàá sì gbélé ayé ṣe rere.



Wednesday, December 18, 2019

O kú ọjọ́ ìbí òní Omidan Àṣà Christiana

Òní ni ọjọ́ ìbí Omidan Oke Christiana, aṣojú réré lo jẹ́ àwokọ́se rere lo sì  jẹ́ fún gbogbo ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá níbi ká wọṣọ àṣà Yorùbá  Ọ̀gá ni kánwú láwùjọ okùta Ọ̀gá ni omidan Tiana níbi ká wọṣọ àṣà Yoruba, Ọ̀gá ni níbi kó dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́.
Gbogbo ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún igbe lárugẹ àṣà àti ìṣẹ̀ṣẹ Yoruba wọn sì kí ọ kú ọjọ́ ìbí





Thursday, December 12, 2019

O kú ọjọ́ ìbí òní Boluwatife

 Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá ló ń bá ẹ yọ̀ tí wọ́n kí ọ kú oriire òní, wọ́n ní o òní kánjú kú, o òní mọ ìnira láyé rẹ, ọdún èyí yóò jẹ ọ̀tun nínú ayé rẹ nítorí pé
Ọdọọdún là ń rórógbó
Ọdọọdún là ń ráwùsá
Ọdọọdún là ń rọ́mọ obì lórí àtẹ

O ku oriire òní Boluwatife



Ìgbáradì ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹhu fún ayẹyẹ ọdún àṣà tí yóò wáyé ní simẹ́sítà tó ń bọ̀

Ìgbáradì ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹhu fún ayẹyẹ ọdún àṣà tí yóò wáyé ní simẹ́sítà tó ń bọ̀

Gbogbo lẹ́bùrù ló fi orin sẹ́nu tí wọ́n sì fi ẹsẹ̀ ra ijó

Ní nkan bíi agogo méjì ó kọjá ìṣẹ́jú díẹ̀ ni ìgbáradì náà bẹ̀rẹ̀.

Aní àwọn ọ̀gá bí Ọ̀mọ̀wé Omolayọ̀ Ọ̀gunlọlá àti Ìyáàfin Taiwo Babátúndé ní ìkàlẹ̀

Àwọn àwòrán tí a yà ní bi ìgbáradì náà:















Monday, December 9, 2019

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá lápapọ̀ kí Oluwakemisola kú oriire ọjọ́ ìbí

Òní ni ọjọ́ ìbí Omidan Olawumi Oluwakemisola Olúwa Toyin
Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè ló ń bá ẹ yọ̀ tí wọ́n kí ọ kú oriire òní, wọ́n ní o òní kánjú kú, o òní mọ ìnira láyé rẹ, ọdún èyí yóò jẹ ọ̀tun nínú ayé rẹ nítorí pé
Ọdọọdún là ń rórógbó
Ọdọọdún là ń ráwùsá
Ọdọọdún là ń rọ́mọ obì lórí àtẹ
O ku oriire òní

Friday, December 6, 2019

Ọ̀gbẹ́ni àti omidan ọ̀sẹ̀ tó yááyì jùlọ

A yan Saheed Fatimah gẹ́gẹ́ bíi omidan to múra jùlọ àti Ògúnníyì Adédayọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọ̀gbẹ́ni tó wọ aṣọ àṣà tó dára jùlọ nínú ìpàdé ètò ìgbáradì fún ọ̀sẹ̀ àṣà wa èyí tó ń bọ̀ lọ́nà ní kò pẹ́ kò jìnà.
 Èyí wáyé láti lè mú kí àṣà ìwọsọ wa láwùjọ Yorùbá má baà parun àti pàápàá láti gbé àṣà wa ga. Àwọn méjèèjì jẹ́ ọmọ ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù tí a sì ṣe èyí láti mú gbogbo àwọn tó kù mọ ìwúlò àti iyì tó wà nínú kí a máa wọ aṣọ ìbílẹ̀ wa ní gbogbo ìgbà.
  A wá fi àsìkò yìí bẹ gbogbo àwọn ọmọ káàárọ̀-o-jíire láti gbìyànjú nínú à ń gbé àṣà wa lárugẹ kí ó má baà parun. Alálẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá á gbè wá o (Àṣẹ)

    Àwòrán Ọ̀gbẹ́ni ọ̀sẹ̀ tó yááyì julọ
Ògúnníyì Adédayọ̀
ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù

Àwòrán omidan ọ̀sẹ̀ tó yááyì julọ
Saheed Fatimah
ọgọ́rùn-ún lẹ́bùrù

Àwòrán àwọn Ọ̀gbẹ́ni àti omidan ẹgbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn 


Omidan àti Ọ̀gbẹ́ni àṣà ẹgbẹ́ 





Saturday, November 30, 2019

Ẹkú Ọjọ́ ìbí òní Mummy DE

Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá kí arábìnrin Atọ́nilà kú oríire ọjọ́ ìbí Kokànlélógójì
Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ èdè panu pọ̀ sọ pé igba ọdún ọdún kan ni láṣẹ Èdùmàrè

ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
ASA DAY 2019
Yosa Unilorin (c)2019